BBC News, Yorùbá - Ìròyìn
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ibi tí ìgbésẹ̀ yíyan Awujale tuntun dé dúró rèé
Idile naa fikun pe ijoko ipade ti yoo waye ni ọjọ Aje ni awọn ti yan awọn ọmọ oye ti wọn yoo fi orukọ wọn ransẹ si awọn Afọbajẹ.
Lẹ́yìn ikú aṣọ́gbó márùn-ún, àwọn agbébọn tún ṣèlérí ìkọlù míràn sí Ikoyi ile
Awọn lẹta ọhun to tẹ ileeṣẹ BBC Yoruba lọwọ ni wọn fi silẹ ni ẹyìn ile kan ti o jẹ ọmọ ìgbìmọ̀ ìjọba ìbílẹ tẹlẹ, Fatai Sa'adu, ní Ọjọru, oṣu kìíní, ọdún 2026.
Bí ẹbí Fusengbuwa ṣe yọ mí kúrò nínú Ọmọ-Oye fún ìtẹ́ Awujale Ijebu lòdì sófin, KWAM 1 kọ lẹ́tà sí Gómìnà
Ninu lẹta ti K1 fi ranṣẹ si Gomina Abiodun nipasẹ agbẹjọro rẹ, Wahab K. Shittu (SAN) lọjọ kẹjọ oṣu Kinni yii, gbajugbaja olorin Fuji naa sọ pe ki ẹbi Fusegbuwa ṣe agbeyẹwo awọn ofin to rọ mọ iyansipo ọba tuntun sori itẹ Awujale, ki wọn si foun naa lanfaani lati dupo ọhun.
Tí Trump bá ṣèkọlù sí Iran, a ṣetán láti gbẹ̀san lára Amẹrika - Ìjọba Iran
Adari ile aṣofin Iran sọ fawọn akẹgbẹ rẹ nile wi pe Iran ṣetan lati ṣe ikọlu si ibudo ologun Amẹrika to wa lẹkun Middle East ati si Israel, ti Amẹrika ba le ṣekọlu si Iran.
Iná jó èèyàn kan pa àti ilé 300 ní Australia
Iroyin ni fun ọpọ ọjọ ni ina ọhun fi jo kaakiri ilẹ naa, paapaa lagbe Victoria ati New South Wales.
Àwọn mọ̀lẹ́bí Chimamanda Ngozi Adichie ní àìbìkítà ilé ìwòsàn ló fa ikú ọmọ rẹ̀
Ọmọdekunrin naa, Nkanu Nnamdi ku sile iwosan niluu Eko lẹyin aisan ranpẹ, eyii to da omi tutu sọkan awọn mọlẹbi rẹ.
Afonja: Ọ̀rẹ́ àjèjì ló kó bá Afọnja, tí Ilọrin fi bọ́ lọ́wọ́ Yorùbá
Afọnja gba ilu Ilọrin labẹ akoso ilu Ọyọ, to si kede pe ilu naa ti di ilu olominira.
Kà nípa Li, ọkùnrin aláàbò ara tó tọrọ báárà àmọ́ tó padà di dókítà
Ọmọ oṣu mẹfa pere n i Li wa ko to lugbadi arun polio.
₦9.3bn ni Tinubu yà sọ́tọ̀ fún Iléeṣẹ́ Ààrẹ, oúnjẹ ati ìrìnàjò ní 2026
Tinubu ni ọjọ kọkandinlogun ọdun 2025 gbe eto isuna lọ siwaju ile igbimọ aṣofin orilẹede Naijiria, ti apapọ owo naa si jẹ N58.18tn.
Wo bí Amala, moimoi, àtàwọn ọ̀rọ̀ míì ṣe wọ ìwé atúmọ̀ èdè Oxford àti ìtumọ̀ tí wọ́n fún wọn
Nínú àtẹ̀jáde ti oṣù Kejìlá, ọdún 2025 tí wọ́n fi léde lójú òpó ìtàkùn ayélujára wọn ṣàfihàn àwọn ọ̀rọ̀ tuntun tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta sínú ìwé atúmọ̀ èdè náà tó fi mọ́ DM, amala, moimoi, brainfart àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ìjọba ilẹ̀ òkèrè dá $9.5m tí àwọn kan jí kó lọ sílẹ̀ wọn padà fún Naijiria
Owo ọhun ni iroyin sọ pe awọn kọlọrọsi ẹda ji ko lọ silẹ naa lọpọ ọdun sẹyin.
Kí nídìí táwọn olùwọ́de fi gba gbogbo ìgboro orílẹ̀ èdè Iran?
Ọjọ́bọ̀ ló pé ọjọ́ kejìlá tí ìwọ́de ti ń wáyé ní orílẹ̀ èdè náà látàrí bí owó ìlú náà ṣe ti já wálẹ̀ lọ́jà àgbáyé, tí ìwọ́de náà sì ti tàn káàkiri àwọn ìlú tó lé ní ọgọ́rùn-ún káàkiri ẹkùn mọ́kànlélọ́gbọ̀n tó wà ní orílẹ̀ èdè náà gẹ́gẹ́ bí àjọ tó ń rí sí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ṣe sọ.
Móríwú
BBC News Yorùbá ti wà lórí ìkànnì WhatsApp
Má jẹ́ kí etí rẹ ó di sí gbogbo ìròyìn ohun tó ń lọ ní Naijiria àti káàkiri àgbáyé. Mọ̀ nípa wọn lórí ìkànnì Whatsapp rẹ
Ìròyìn Àkàgbádùn
Àwọn orílẹ̀ èdè wo ni Trump tún ń fojúsùn lẹ́yìn Venezuela?
Ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè ni Trump ti ń fojúsùn láti ṣe ìkọlù sí.
Ta ni Ọ̀mọ̀wé Olugbemisola Odusote, Adarí Obìnrin àkọ́kọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga àwọn Amòfin tí Tinubu ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn sípò?
Atẹjade kan ti Oludamọran fun Aarẹ lori eto iroyin, Bayo Onanuga, fi sita lọjọ Iṣẹgun ana, fidi iyansipo naa mulẹ.
Àlàyé lórí òfin tuntun tí UK gbé kalẹ̀ lórí àwọn tó ń fi ọkọ̀ ojú omi káwọn àjèjì wọlé
Awọn ẹṣọ aṣọbode yoo maa gba foonu awọn to n lo ọkọ oju omi lati japa lọ si UK ni toootọ, amọ, eyi ko tumọ si pe wọn maa fọwọ ofin mawọn eeyan naa.
Kí làwọn àtúntò tí ìjọba Nàìjíríà mú bá ètò ìdánwò WAEC àti NECO láti dènà àwọn aṣemáṣe?
Ètò ìdánwò WAEC àti NECO ló wà fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ girama tí wọ́n wà ní ipele àṣekágbá, tí wọ́n sì ń múra láti lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga.
Ìjọba mi yóò rí i dájú pé irú ìkọlù yíì kò ṣẹlẹ̀ mọ́- Gómìnà Seyi Makinde
Gomina Makinde ṣalaye pe iwadii awọn ẹṣọ alaabo fi han, pe awọn agbesunmọmi to ti ẹnu ibode ibomiran wa lo ṣe iṣẹ ibi naa.
Ṣé lóòótọ́ ni pé agbébọn làwọn èèyàn mẹ́fà táwọn ọmọ ogun mú ní ìpínlẹ̀ Edo pẹ̀lú ọkọ̀ ìjọba ìbílẹ̀ Kwara?
Ninu osu Kejila, ọdun to kọja ni fọnran kan gba ori ayelujara eyi to ṣafihan awọn eeyan mẹfa kan ti wọn dọbalẹ, tawọn kan n beere nnkan lọwọ wọn.
Kí ló ń fa fàákája láàrin Wike àti akọ̀wé APC, tí Sẹ́nẹ́tọ̀ Basiru fi ní kí Wike kọ̀wé fipò mínísítà sílẹ̀? Àlàyé rèé
Sẹnẹtọ Basiru ni ọrọ ti Wike sọ tabuku oun ati ọfiisi oun gẹgẹ bii akọwe agba ẹgbẹ oṣelu APC, tori nnkan toun sọ wi pe gbogbo ọmọ ẹgbẹ igbimọ amuṣẹya NWC APC gbọdọ fawọn gomina to wa nipo lọwọ ni ọwọ to tọ si wọn.
Ìyàtọ̀ láàrin òfin owó orí tuntun tó wà lákọsílẹ̀ ìjọba àti èyí tílé aṣòfin buwọ́lù, ìdí táwọn aṣòfin fi figbe ta
Lopin ọsẹ to kọja ni ile aṣoju-ṣofin l'Abuja fi ẹda ofin naa sita, eyi ti Aarẹ Tinubu buwọlu.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo dá olóyè Ofiki dúró lórí ìwakùsà lọ́nà àìtọ́
Ninu lẹta ti adari ẹka to n ri si ọrọ oye ni ileeṣẹ to ri n si ijọba ibilẹ ati oye jijẹ ti ipinlẹ Oyo, Olajire Moses Aloo fọwọ si fi ẹsun kan Oloye Jacob Shobaloju pe o n buwolu iwe aṣẹ fawọn ileeṣẹ kan lati maa wakusa ni awọn agbegbe kan atawọn igbo ọba lai gba aṣẹ latọdọ ijọba.
Pásítọ̀ tó ní ayé yóò parẹ́ lọ́jọ́ Kérésì, kan ọkọ̀ ńlá, dèrò àhámọ́
Bi ọjọ Keresi ṣe n sunmọle, awọn Kristẹni kan tu yaaya lọ sibi ọkọ Ebo Noah, wọn fẹ wọle ki ẹkun omi ma baa pa wọn.
Fídíò, Ẹ bá mi rọ Ọba Ghandi kó má tún ìtàn Ògbórí Ẹlẹ́mọ̀ṣọ́ yà- Ẹda Onile Ola, Duration 3,57
Alagba Lere Paimo ni bi wọn ba fẹe ya itan Ogbomoso, o kunlẹ, dandan kọ ni ko jẹ Ogbori Elemọṣọ.
Àwọn ajínigbé tún jí èèyàn mẹjọ gbé ní Kwara
Iṣẹlẹ naa waye ni nnkan bi aago meje owurọ ni opopona Isanlu isin si Omu-Aran gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ.
Kọ́milẹ́kọ̀ọ́
Ẹ tẹ̀lé wa lórí ìkànnì ayélujára
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìjọba Kwara bẹ̀rẹ̀ ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ lórí rédíò fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ nítorí ìkọlù àwọn ajínigbé
Olohungbebe ní dídá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ dúró sílé láwọn agbègbè tí ètò ààbò ti nílò àmójútó níbẹ̀ gidi jẹ́ ọ̀nà láti fi dá ààbò bo àwọn olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ ní agbègbè náà.
America fẹ́ẹ́ pa mi nínú ìkọlù, wọ́n ní Boko Haram ni mi-Sheikh Gumi
Gumi ni America n kede pe oun fẹ gba Naijiria la, lati ba awọn agbesunmọmi ja, ṣugbọn awọn gan-an ni agbesunmọmi.
Lẹ́yìn oṣù mọ́kànlá, àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ padà sẹ́nu iṣẹ́ nípìnlẹ̀ Osun
Ti ẹ ko ba gbagbe pe, ọjọ Keje, osu Keji ọdun 2025 ni awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ ni ipinlẹ Osun ti lọ si ọfiisi gbẹyin latari ifanfa to n waye lori awọn alaga ijọba ibilẹ.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí pásítọ̀ Chris Okafor táwọn obìnrin fẹ̀sùn kan pé ó fipá báwọn lòpọ̀
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní pásítọ̀ náà, tó jẹ́ pásítọ̀ àgbà nínú ìjọ Mountain of Liberation and Miracles Ministries, ìpínlẹ̀ Eko máa kojú ìwádìí tó lágbára.
Àwọn agbébọn yawọ ọjà, ṣekúpa èèyàn 30, jí ọ̀pọ̀ gbé lọ
Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Niger, Wasiu Abiodun fi léde lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ́ Kẹrin, oṣù Kìíní fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé èèyàn tó lé ní ọgbọ̀n ni wọ́n ṣekúpa níbi ìkọlù náà.
Wo ọjọ́ tí Ramadan yóò bẹ̀rẹ̀, ọjọ́ Àjíǹde, àti àwọn ọjọ́ ìsinmi tí ìjọba yóò kéde ní 2026
Yatọ si awọn eyi tijọba yoo kede awọn miiran wa to ṣe pe ikede kankan ko ni waye lori wọn sugbọn awọn eeyan yoo ṣami wọn tori pe ọjọ pataki ni fun wọn.
Makinde ṣe àtúntò ìgbìmọ̀ aláṣẹ ìjọba Ìpínlẹ̀ Oyo, yọ Akọ̀wé ìjọba nípò
Gẹgẹ bi atẹjade kan ti oludamọran gomina lori eto iroyin Sulaimon Olanrewaju fi sita; Makinde ti yọ akọwe ijọba ipinlẹ Oyo, Ọjọgbọn Olanike Kudirat Adeyemo atawọn mii nipo.
Ààrẹ Tinubu pàṣẹ káwọn olórí ogun wá àwọn agbébọn tó pa èèyàn tó lé lógójì nípìnlẹ̀ Niger jáde
Tinubu dari aṣẹ naa si Minisita eto aabo, Olori awọn ẹṣọ alaabo, awọn ọga ologun ẹka kọọkan, ọga ọlọpaa patapata ati adari ẹka ọtẹlẹmuyẹ lorilẹede yii.
Mi ò fipò sílẹ̀ nítorí mo ṣe nǹkan tí kò tọ́, ṣùgbọ́n nítorí mo bọ̀wọ̀ fún ọ́fíìsì mi-Kemi Adeosun
Saaju ninu ọrọ Adeosun lọdun 2022, o ni ojoojumọ ni òun fi ń wa ẹkún mu fún oṣù mẹ́ta láì ṣe iṣẹ́ kankan.









































































